HYMN 207

t. C.M.S. 86 t.H.C. 553, (FE 227)
"Awa omo yo, inu wa yio si ma dun"
- Ps.118:241. ONIGBAGBO, e bu s’ ayo, 

   Ojo nla l’eyi fun wa;

   E gbo bi awon Angeli,

   Ti nfi Ogo fun Olorun, 

   Alafia, Alafia,

   Ni fun gbogbo enia.


2. Ki gbogbo aiye ho f‘ ayo; 

   K‘ a f'ogo fun Olorun; 

   Omo bibi Re l’ O fun wa; 

   T‘ a bi ninu Wundia, 

   En’lyanu, En‘ Iyanu,

   Ni Omo t’a bi loni.


3. Ninu gbogbo rudurudu 

   Ohun ibi t’ okun aiye, 

   Ninu idamu nla ese, 

   L’ Om’ Olorun wa gba wa; 

   Olugbimo, Olugbimo, 

   Alade alafia.


4. Olorun Olodumare;

   L’ a bi. bi omo titun; 

   Baba! Eni aiyeraiye; 

   L’odi alakoso wa:

   E bu s‘ayo, E bu s’ayo 

   Omo Dafidi joba.


5. O wa gba wa lowo ese, 

   O wad‘onigbowo wa, 

   Lati fo itegun esu,

   A se ni Oga ogo:

   E ku ayo, e ku ayo,

   A gba wa lowo iku. Amin

English »

Update Hymn