HYMN 21

C.M.S 25, H.C 218 t (FE 38) H.C 96D, 
7S 6s
"Ojo Oluwa" - Ifi. 1:10s


1. OJO isimi at’ayo

   Ojo inu didun; 

   Ogun fun ibanuje 

   Ojo dida julo

   Ti awon eni giga 

   Niwaju ite Re 

   Nko mimo, mimo, mimo 

   S’eni Metalokan.


2. L’ojo yi ni ‘mole la, 

   Nigba dida aiye

   Ati fun igbala wa 

   Kristi jinde loni, 

   L‘ojo oni l’Oluwa 

   Ran Emi torun wa; 

   Ojo ologo julo

   T’o ni mole pipe.


3. Orisun ‘tura ni O, 

   L’aiye aginju yi,

   L’ori Re, bi ni Pisga 

   L’a nwo ‘le ileri 

   Ojo ironu didun 

   Ojo ife mimo

   Ojo ajinde, lati 

   Aiye si nkan orun.


4. L’oni s’ilu t’are mu, 

   Ni manna t’orun bo, 

   Si ipejopo mimo 

   N’ipe fadaka ndun, 

   Nibiti ihin-rere, 

   Ntan imole mimo 

   Omi iye nsan jeje

   Ti ntu okan lara.


5. K’a r’ore‐ofe titun 

   L’ojo ‘simi wa yi

   Ka si de simi t’o ku 

   F’awon alabukun 

   Nibe ka gbohun soke 

   Si Baba at’Omo

   Ati si Emi Mimo

   N’iyin Metalokan. Amin

English »

Update Hymn