HYMN 211

H.C. 82 2nd 2nd Ed., H.C. 247 
D.S.M., C.M.S. 88 (FE 230)
"Niwon igba die enyin osi ri mi” - John 16:16
1. LEHIN odun die, 

   Lehin igba die,

   A o kowa jo pel’ awon

   Ti o sun n‘iboji.

Egbe: Oluwa, mu mi ye, 

      Fun ojo nlanla na!

      Jo, we mi ninu eje Re,

      Si ko ese mi lo.


2. Lehin ojo die, 

   Laiye buburu yi,

   A o de b' orun ko si mo, 

   Ile daradara.

Egbe: Oluwa, mu mi ye...


3. Lehin igbi die; 

   L’ebute lile yi,

   A o de b’ iji ko simo, 

   T' okun ki bu soke.

Egbe: Oluwa, mu mi ye...


4. Lehin ‘yonu die; 

   Lehin ‘pinya die;

   Lehin ekun ati aro,

   A ki sokun mo. 

Egbe: Oluwa, mu mi ye...


5. Ojo‘simi die,

   La ni tun ri laiye;

   A o de ibi isimi, 

   Ti ki o pin lailai.

Egbe: Oluwa, mu mi ye...


6. Ojo die l'o ku, 

   On o tun pada wa,

   Eniti o ku k’awa le ye, 

   K’ a ba le ba joba.

Egbe: Oluwa, mu mi ye, 

      Fun ojo nlanla na!

      Jo, we mi ninu eje Re,

      Si ko ese mi lo. Amin

English »

Update Hymn