HYMN 212

C.M.S. 91 H.C. 99 P.M. (FE 231)
“Beni ki Iwo ki o ko wa lati ma
ka Iye ojawa, ki awa ki ole fi 
okan wa sipa ogbon" - Ps. 90:12
1. OJO ati akoko nlo,

   Nwon nsun wa s‘ eti, ‘boji, 

   Awa fere dubule na,

   Ninu iho ‘busun wa.


2. Jesu, ’Wo Olurapada,

   Ji okan t’ oku s’ ese;

   Ji gbogbo okan ti ntogbe, 

   Lati yan ipa iye.


3. Bi akoko ti nsunmole, 

   Jek’ a ro ‘ bi ti anlo; 

   Bi lati r’ayo ailopin, 

   Tabi egbe ailopin.


4. Aiye wa nlo!

   Iku de tan,

   Jesu, so wa,

   Tit' O fi de,

   K’a a ba O gbe,

   K’ aba O ku,

   K‘ a ba O joba titi lailai.


5. Aiye wa nkoja b’ ojiji, 

   O si nfo lo bi ‘kuku; 

   Fun gbogbo odun t’ o 

   K oja,

   Dariji wa, mu wa gbon.


6. Ko wa lati ka ojo wa,

   Lari ba ese wa ja,

   K'a ma sure, k’ a ma togbe, 

   Tit'a o fi ri ‘sinmi.


7. Gbogbo wa fere duro na, 

   Niwaju ite ‘ dajo;

   Jesu, ‘ Wo t’o segun iku, 

   Fi wa s' apa otun Re.


8. Aiye wa nlo!

   Iku de tan, Olugbala!

   Jo pa wa mo, K’ a ba O gbe, 

   K’a ba O ku,

   K’ a ba O joba titi lailai. Amin

English »

Update Hymn