HYMN 215

(FE 234) (Ki a to bere si jagun) 
Tune: Iya ni wura iyebiye1. KI gbogbo ojubo Oro d’oko, 

   T' Ora t‘ Ogun ati t‘Esu,

   ki nwon dojubo Jesu Oba, 

   L’ adura Egbe Serafu. 

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire,

      Tire sa ni wa titi aiye, 

      Nitori Kristi Omo Baba, 

      Da wa sil’ Egbe Sarafu.


2. Ki gbogbo ojubo Irunmole, 

   Ti Sango ati Sonponna,

   Ki nwon dojubo Jesu Oba, 

   L’dura egbe Serafu.

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


3. Ki gbogbo ojubo Irunmole, 

   T' lfa ati t‘oba laiye,

   Ki nwon dojubo Jesu Oba, 

   L’ adura egbe Serafu. 

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


4. Ki gbogbo ojubo risa loko, 

   Ti babaji ati Osun,

   Ki nwon dojubo Jesu Oba,

   L’ adura Egbe Serafu. 

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


5. K’awon agbagba leyipada, 

   Ati Oba Osemowe,

   Ki nwon le juba Jesu Oba, 

   L’adura Egbe Serafu. 

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


6. Ki gbogbo ojubo Olorun, 

   Ti‘ gunnu ati Gelede,

   Ki nwon dojubo Jesu Oba,

   L’adura Egbe Serafu. 

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


7. K'awon Keferi le yipada, 

   At'awon Elegun pelu,

   Ki nwon lejuba Jesu Oba, 

   L’ adura Egbe Serafu. 

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


8. K'awon oloya le yipada, 

   A t’ awon alagemo,

   Ki nwon le juba Jesu Oba,

   L’adura Egbe Serafu. 

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


9. Ki gbogbo om'Egbe Serafu, 

   At‘ Egbe Kerubu pelu,

   Ki nwon lejuba Jesu Oba, 

   Lati se ise won dopin.

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


10. Ki gbogb’ awon Egbe Akorin, 

    Ati Egbe Aladura;

    Ki Egbe lgbimo Serafu,

    Ki nwon d’amure won giri.

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


11. K’Olorun da alagba wa si, 

    Ati awon lsongbe re; 

    K’Olorun tubo ran nyin lowo, 

    K' O di nyin l'amure ododo. 

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire...


12. K'a fi ogo fun Baba l‘oke,

    k'a f' ogo fun Omo pelu,

    K' a fi ogo fun Emi Mimo 

    Metalokan l'ope ye fun.

Egbe: Oluwa, se wa ni Tire,

      Tire sa ni wa titi aiye, 

      Nitori Kristi Omo Baba, 

      Da wa sil’ Egbe Sarafu. Amin

English »

Update Hymn