HYMN 216

SS 455 (FE 235)
"Ma tan, Iwa lrawo" - Ifi. 22:161. MA tan, Irawo didan, 

   Lat’ Ile Re loke;

   Ma fi ‘feran Baba han, 

   N'nu titan didan Re. 

Egbe: Ma tan, ma tan,

      Iwo lrawo didan, 

      Ma tan, ma tan,

      Iwo Irawo didan.


2. Ma tan, Irawo Ogo, 

   A gboju wa si O;

  Li oke awosanma, 

  Awa nri ‘tansan Re. 

Egbe: Ma tan, ma tan...


3. Ma tan, ‘wo ti ki paro, 

   Ko si s’amona wa; 

   Sibi t’imole ayo,

   Ti ko lopin gbe wa.

Egbe: Ma tan, ma tan...


4. ‘Gba ba si d’orun pelu, 

   Awon t’arapada; 

   k’a wa pelu Re n'nu Ogo, 

   Le ma tan titi lai.

Egbe: Ma tan, ma tan,

      Iwo lrawo didan, 

      Ma tan, ma tan,

      Iwo Irawo didan. Amin

English »

Update Hymn