HYMN 217

“lfe l'akoja ofin" (FE 236)1. JESU loruko to gaju,

   Laiye ati lorun;

   Awon Angeli wole fun, 

   Esu, beru o sa.

Egbe: Ha! ko s' ariyanjiyan mo,

      Ipe miran ko si,

      O daju wipe Jesu ku, 

      A ni f' emi elese.

2. Kerubu ati Serafu,

   Nwon yi ‘te Baba ka,

   Nigba gbogbo niwaju Re 

   Nwon nko orin iyin.

Egbe: Ha! ko s' ariyanjiyan...


3. Olugbala segun iku,

   ljoba Satan fo;

   Gbogho eda e bu sayo,

   Ka yin Baba logo,

Egbe: Ha! ko s' ariyanjiyan...


4. Kerubu ati Serafu,

   E feran ara yin;

   lfe ni awon Angeli,

   Fi nsin Baba loke.

Egbe: Ha! ko s' ariyanjiyan...


5. Jesu, Olori Egbe wa,

   Bukun wa laiye wa;

   Jowo pese fun aini wa,

   K’ ebi ale ma pa wa.

Egbe: Ha! ko s' ariyanjiyan...


6. Jehovah-Jire Oba wa, 

   Iyin f‘ oruko Re; 

   Ma jeki oso at‘aje,

   Ri wa lojo aiye wa.

Egbe: Ha! ko s' ariyanjiyan...


7. Jesu, fo itegun esu,

   Iwo l'Oba Ogo;

   lyin ope ni fun Baba,

   Ni fun Metalokan.

Egbe: Ha! ko s' ariyanjiyan mo,

      Ipe miran ko si,

      O daju wipe Jesu ku, 

      A ni f' emi elese. Amin

English »

Update Hymn