HYMN 224

Tune: D 7s 6s Duro, Duro, Duro1. ODUN miran tun ti de 

   Baba mi je k‘o je 

   Odun miran pelu Re 

   N'nu 'se tab' isinmi 

   Odun itesiwaju 

   Odun miran fun iyin 

   Odun miran lati mo 

   Wiwa Re n'gbogbojo.


2. Odun miran fun aanu 

   F’ooto at'oor'ofe 

   Odun miran fun ayo 

   Fun ogo oju Re 

   Odun mii' lati sinmi 

   L'ookan aya ‘fe Re 

   Odun ti n o gbekele E 

   Pelu sinni didun.


3. Odun miran fun isin 

   Fun ‘jen' ife Re

   Odun miran fun eko 

   Fun ‘se mimo‐l’oke 

   Odun miran tun ti de 

   Baba mi je k'oje

   Odun miran pelu Re 

   L‘aye tabi l'orun. Amin

English »

Update Hymn