HYMN 225

C.M.S 97 t.H.C 43 D. 7s. (FE 224)
"Kili emio nyin?” - Jak. 4:14 1. ODUN miran ti koja

   Wawa l’akoko na lo 

   Nini eyit'a wa yi

   Yio s'arimo opo

   Anu l’o fi da wa si

   A ha lo anu na bi?

   K’a bi ‘ra wa ba se tan? 

   B'a o pe wa l’odun yi.


2. Aiye bi ibi ija 

   Egbegberun l'o nsubu 

   Ofa iku t’o si nfo

   A le ran s’emi b'iwo 

   Nigb’ a nwasu t’a si ngbo 

   Oluwa, jek’a saro 

   P'aiyeraiye sunmole

   A nduro l’eti bebe.


3. B’a gba wa lowo ese

   Nipa ore-ofe Re

   Nje ‘ma bo’ n' ipe o je

   K'a le lo, k'a r’oju Re 

   F'enia Re l’aiye yi

   K’anu wa l'odun titun

   Odun t'o l’ayo ju yi 

   L'eyi t’o mu won de ‘le. Amin

English »

Update Hymn