HYMN 226

(FE 245)
"Fi ayo sin Oluwa” - Ps. 100:21. OJO ayo l‘ojo oni

   Enyin Angeli e wa ba wa yo 

   Fun ayo nla t’o sokale 

   S‘arin Egbe Serafu t'aiye.

Egbe: Ogun orun, e ba wa yo 

     Gbohun nyin ga enyin Serafu 

     E ba wa yo ayo oni

     E korin iyin si, Metalokan.


2. Okan wa yin Oba orun 

   Emi wa yo si Olorun wa

   O ti siju anu wo wa

   Ko si jek’awon ota yo wa. 

Egbe: Ogun orun, e ba wa...


3. Enyin Angeli e ba wa bo 

   Enyin ti nri lojukoroju 

   Orun, Osupa, e wole

   Ati gbogbo aiye e juba.

Egbe: Ogun orun, e ba wa...


4. O ti fi agbara Re han 

   F’awon iran ti o ti koja

   Jeje lo nto wa lona Re

   O si ngba wa lowo ota wa.

Egbe: Ogun orun, e ba wa...


5. O mu alagbara kuro

   O gbe talika sori ite

   Tali a o ha yin bi Re

   E yin, eyin gbogbo aiye yin. 

Egbe: Ogun orun, e ba wa...


6. Baba orun, awa dupe

   Fun anu re l‘ori Egbe wa 

   Eyin, e yin gbogbo aiye 

   Enyin orun e juba Jesu.

Egbe: Ogun orun, e ba wa yo 

     Gbohun nyin ga enyin Serafu 

     E ba wa yo ayo oni

     E korin iyin si, Metalokan. Amin

English »

Update Hymn