HYMN 228

11.11.11.11
Tune: "E ma tesiwaju"1. N'bere odun yi, odun titun yi 

   Oro itunu de, ti nle eru lo

   Ohun keje jeje, ti Baba orun 

   Ododo l’oro na, ti nm'okan wa yo.

Egbe: E ma tesiwaju, 

      omo imole

      Oro Re ko le ye, 

      O nduro titi.


2. Ma beru ‘loro na, Mo wa pelu yin 

   Emi n’iranwo yin at’agbara yin 

   Emi y'o di yin mu, li owo ‘tun mi 

   Mo pe yin, mo yan yin, lati je

   temi titi.

Egbe: E ma tesiwaju..


3.  Fun opo odun ti mbe niwaju wa

   Opo ni ipese t'awon seleri

   lpese f‘alaini f'awon elese

   F'awn t'a npon loju, fun alailera wa. 

Egbe: E ma tesiwaju..


4. Ko je fi wa sile, ko si ni ko wa 

   Majemu Re daju ti ko le ye Iae

   A ro mo ‘leri yi, eru ko ba wa 

  Olorun wa ti to, fun odun ti mbo.

Egbe: E ma tesiwaju, 

      omo imole

      Oro Re ko le ye, 

      O nduro titi. Amin

English »

Update Hymn