HYMN 231

6s. 8s (FE 251)
"Olubukun li Oluwa" - Ps. 124:6 
Ohun Orin: "Eyo Jesu Joba“1. AWA onigbagbo 

   T'o wa ninu ese 

   K’a f‘ope f'Olorun 

   To da wa si doni.

Egbe: Arakunrin, arabinrin 

      E ku odun; e ku 'yedun x2


2. Jesu, Oluwa wa 

   Emi airi nso wa

   Eni nku lo y'o ye 

   Alaisan yio dide. 

Egbe: Arakunrin, arabinrin...


3. Oba Ologo meta 

   Eni Metalokan

   Gbogb’ eda njuba Re 

   Loke ati ‘sale. 

Egbe: Arakunrin, arabinrin...


4. Odun to koja lo

   Ko ni ‘gbagbe l'o je

   Akopo enia

   Arun nti won sorun. 

Egbe: Arakunrin, arabinrin...


5. Ise ko si lode

   Oja ko tun la mo

   Opo ti sa kuro

   Fun ‘gbese adako.

Egbe: Arakunrin, arabinrin...


6. Jehovah Jire wa
 
   Yio so wa lodun yi 

   Jehovah Nissi wa

   Ti tele f’enia re. 

Egbe: Arakunrin, arabinrin...


7. Ko seru mo lode 

   B’Olorun je tiwa 

   Amin, Amin, Ase 

   Dandan ko le sai se. 

Egbe: Arakunrin, arabinrin 

      E ku odun; e ku 'yedun 

      E ku odun; e ku 'yedun. Amin

English »

Update Hymn