HYMN 241

(FE 261)
C.M.S. 182, H.C. 377 8.5.8.3 
"Enikeni ti o ba nsin mi ki o ma to mi 
lehin; nibiti mo ba wa nibe ni iranse 
mi yio ma gbe pelu.” - John 12:261. ARE mu o aiye su o 

   Lala po fun o?

   Jesu ni, ‘Wa si odo mi 

   K’o simi.


2. Ami wo l’emi o fi mo 

   Pe On l‘o npe mi? 

   Am’iso wa lowo,

   ati Ese Re.


3. O ha ni ade bi Oba 

   Ti mo le fi mo? 

   Toto, ade wa lori Re, 

   T’egun ni.


4. Bi mo ba ri, bi mo tele 

   Kini ere mi?

   Opolopo iya ati 

   'Banuja.


5. Bi mo tele tit’aiye mi 

   Kini ngo ri gba? 

   Ekun a dopin, o simi 

   Tit‘aiye.


6. Bi mo bere pe ki O gba mi, 

   Y'o ko fun mi bi?

   B'orun at'aiye nkoja lo 

   Ko je ko.


7. Bi mo ba ri, ti mo ntele 

   Y’o ha bukun mi? 

   Awon ogun orun wipe 

   Yio se. Amin

English »

Update Hymn