HYMN 245

C.M.S 145 H.C. 145 7s (FE 265) 
“Olorun sanu fun mi, elese”
Luku 18:131. ELESE mo nfe ‘bukun 

   Onde: mo nfe d’omnira 

   Alare: mo nfe simi 

   “Olorun, sanu fun mi.”


2. Ire kan emi ko ni

   Ese sa l‘o yi mi ka

   Eyi nikan l'ebe mi 

   “Olorun, sanu fun mi."


3. lrobinuje okan!

   Nko gbodo gboju s'oke 

   Iwo sa mo edun mi 

   “Olorun, sanu fun mi.”


4. Okan ese mi yi nfe

   Sa wa simi laiya re

   Lat'oni, mo di Tire

   “Olorun, sanu fun mi.”


5. Enikan mbe l'or ite 

   Ninu Re nikansoso 

   N'ireti at’ebe mi 

   “Olorun, sanu fun mi.”


6. On o gba oran mi ro 

   On ni Alagbawi mi 

   Nitori Tire nikan

   “Olorun, sanu fun mi.” Amin

English »

Update Hymn