HYMN 25

E.O. 21, S.D.M. (FE 42)
d.r.m.:r.d.l:s:d:-d:r:d:r:m:r:‐
"E ho iho ayo si Olorun" - Ps. 66:1


1. OLUWA awa de,

   Lati yin O logo

   Fun ayo nla t'a nyo loni 

   Larin Egbe Seraf 

Egbe: Olugbala, a de

      Lati f'iyin fun O

      Ogo, Iyin, f'Oruko Re

      Alagbara julo etc


2. Kerubu, Serafu 

   Eyin ni’yo aye

   llu ta te sori oke

   A ko le farasin 

Egbe: Olugbala, a de...


3. Kabiyesi! Oba,

   Ogo f'Oruko Re!   

   Fun iyanu Re larin wa, 

   Eyi t'a ko gbo ri 

Egbe: Olugbala, a de...


4. Orin Halleluyah! 

   L'awa yio ma ko

   Awa y‘o f‘iye fo b’idi 

   Lehin irin ajo wa. 

Egbe: Olugbala, a de...


5. Aiye sun m'Olorun 

   Akoko sunmo le: 

   Ilekun anu fere ti, 

   E wa wo oko na. 

Egbe: Olugbala, a de...


6. Jesu, Olori wa,

   A gb'oju wa si O,
 
  ‘Wo l’ao ma yin titi aiye, 

  Aiye ainipekun 

Egbe: Olugbala, a de...


7. A f'ogo fun Baba

   A f'ogo f‘Omo Re 

   Ogo ni fun Emi Mimo 

   Metalokan Iailai. 

Egbe: Olugbala, a de... Amin

English »

Update Hymn