HYMN 251

C.M.S 157.H.C.162 L.M (FE 271)
“Nigbana ni o sanu fun, o si wipe gba kuro 
ninu lilo sinu: iho, emi to ri irapada"
 - John. 33:241. BI mo ti kunle, Oluwa

   Ti mo mbe f’anu lodo Re 

   Wo t’Ore lese ti nku lo 

   Si tori Re gb'adura mi.


2. Ma ro ‘tiju at' ebi mi

   At' aimoye abawon mi 

   Ro t’eje ti Jesu ta ‘le 

   Fun ‘dariji on iye mi.


3. Ranti bi mo ti je Tire

   Ti mo je eda owo Re 

   Ro b'okan mi ti fa s’ese 

   Bi danwo si ti yi mi ka.


4. A! ronu oro mimo Re 

   Ati gbogbo ileri Re 

   Pe ‘Wo o gbo adua titi 

   Ogo Re ni lati dasi.


5. A! ma ro ti ‘yemeji mi 

   Ati ailo or-ofe Re

   Ro ti omije Jesu mi

   Si fi toju Re di temi


6. Oju on eti Re ko se

   Agbara Re ko le ye lai

   Jo wo mi; okan mi wuwo 

   Da mi si, k’O ran mi lowo. Amin

English »

Update Hymn