HYMN 253

C.M.S 160 H.C 548. C.M. (FE 273) 
“Gba mi la nitori anu Re" - PS. 6:41. BABA, ma yi oju kuro 

   Fun emi otosi 

   Ti npohunrere ese rni 

   N’iwaju ite Re.


2. ‘Lekun anu to si sile 

   F’ akerora ese

   Mase ti mo mi, Oluwa 

   Je ki emi wole.


3. Emi ko nipe mo njewo 

   B’aiye mi ti ri ri

   Gbogbo re lat’ehin wa, ni 

   'Wo mo dajudaju.


4. Mo wa si ‘lekun anu Re 

   Nibiti anu po

   Mo fe ‘dariji ese mi 

   K’O mu okan mi da.


5. Emi ko ni ma tenumo 

   ltunu ti mo nfe

   'Wo mo, Baba, ki nto bere 

   lbukun t’emi nwa.


6. Anu, Oluwa, ni mo fe 

   Eyiyi l’opin na 

   Oluwa, anu l’o ye mi 

   Je ki anu Re wa. Amin

English »

Update Hymn