HYMN 256

C.M.S. 172 H.C 159 8s.6.9 (FE 276)
“Enikeni ti o to mi wa, emi ki yio 
ta nu bi o ti wu ki o ri" - John 6:37
1. BI mo ti ri laisawawi 

   Sugbon nitori eje eje Re 

   B'O si ti pe mi pe ki nwa 

   Olugbala, mo de.


2. Bi mo ti ri, laiduro pe 

   Mo fe k'okan mi mo toto 

   Sodo Re t'o le we mi mo 

   Olugbala, mo de.


3. Bi mo ti ri, b’o tile je 

   Ija lode, ija ninu 

   Eru lode, eru ninu 

   Olugbala, mo de.


4. Bi mo ti ri: osi, are 

   Mo si nwa imularada 

   Iwo lo le s'awotan mi 

   Olugbala, mo de.


5. Bi mo ti ri: ‘Wo o gba mi 

   ‘Wo o gba mi towo-tese 

   “Tori mo gba ‘leri Re gbo 

   Olugbala, mo de.


5. Bi mo ti ri: Ife Tire

   Lo sete mi patapata

   Mo di Tire, Tire nikan 

   Olugbala, mo de. Amin

English »

Update Hymn