HYMN 259

C.M.S.175 H.C 169 8s 7s 11 (PE 279)
"Enikeni ti o ba si ki o gba omi iye 
na Iofe” - Ifi. 22:17



1.  OTOSI elese, e wa

     Wa ni wakati anu

     Jesu setan lati gba nyin

     O kun f’anu at’ife

     O si le se, O mura tan, ma foiya.


2.  Enyin alaini, e wa gba 

     Ogo Olorun l’ofe 

     ‘Gbagbo toto, ‘ronu toto 

     Or’ofe ti o nfa wa

     Wa ‘do Jesu, alaini owo 

     sa wa ra.


3.  Ma je k’okan nyin da nyin ro 

     Mase ro ti aiye nyin
  
     Gbogbo yiye t’o mbere ni

     Ki e sa mo aini nyin

     ‘Yi l‘o fun nyin; tansan 

     Emi l‘okan.


4.  Enyin t’eru npa, t’are mu, 

     T’e sonu t‘e si segbe

     Bi e duro tit’ eo fi san

     E ki yio wa rara

     F’elese ni, On ko wa f’olododo.


5.  Olorun goke l‘awo wa

     O nfi eje Re bebe

     Gbe ara le patapata

     Ma gbekele ohun mi 

     Jesu nikan l'o le elese l’ore.


6.  Angeli at’ awon mimo 

     Nkorin ‘yin Od’agutan 

     Gbohungbohun Oruko Re

     Si gba gbogbo orun kan 

     Halleluya! elese le gberin na.  Amin

English »

Update Hymn