HYMN 268

(FE 288)
"A dari ese re ji " - Luku 5:201. ’WO ti npafo ninu ese

   Kristi npe o wa sodo Re 

   O ti so eru ese re

   Wa sinu agbo Jesu. 

Egbe: Kristi npe o wa sodo Re

      On I' O ni igbala kikun 

      Jesu nduro O nreti re 

      Wo yio ha ko ipe Re.


2. Olugbala wa s’aiye yi 

   Lati wa ra o pada 

   Lowo ese ati arun

   lgbala wo lo to yi?

Egbe: Kristi npe o wa sodo...


3. Bo ti wu k‘ese re po to 

   Kristi nfe so O di mimo 

   O ti pari ‘se gbala yi

   O ku sowo re, ma bo.

Egbe: Kristi npe o wa sodo...


4. Kristi npe o Iati ronu 

   Aye mbe sibe fun o 

   Wa, mase kiri ‘nu ese 

   Aiye ko lere fun o.

Egbe: Kristi npe o wa sodo...


5. B’aiye at‘ esu nde si o 

   Ti ‘ponju bo o mole 

   Wa si abe abo Kristi 

   Nibe a o ri isimi.

Egbe: Kristi npe o wa sodo Re

      On I' O ni igbala kikun 

      Jesu nduro O nreti re 

      Wo yio ha ko ipe Re.  Amin

English »

Update Hymn