HYMN 27

C.M


1.  JE k‘a yin Oluwa isimi

Pelu awon Mimo

Ti nf'ayo at'orin didun 

Lo s‘simi ailopin.


2.  Oluwa, b'a ti nranti Re 

N'ibukun wa npo si 

Nipa orin iyin l'a nko 

B‘a ti y'ayo ‘segun.


3.  Lojo ayo yi l‘Olorun

Oro ayeraye

F‘ise nla han, t'o logo ju 

Ti iseda aye.


4.  O jinde, eni f’irora 

Ra gbogb’ eda pada 

Ise nla ni dida aye 

Idande ju yi lo.  Amin


English »

Update Hymn