HYMN 270

C.M.S 168 H.C. 229 7s E. (FE 290)
"Oluwa, odo Re ni mo sa pamo si"
 - Ps. 143:91. JESU Oluf'okan mi 

   Je ki nsala s‘aiya Re 

   Sa t'irumi sunmo mo 

   Sa ti iji nfe s'oke 

   Pa mi mo, Olugbala 

   Tit’iji aiye y'o pin

   To mi lo s‘ebute Re 

   Nikehin gba okan mi.


2. Abo mi, emi ko ni 

   Iwo lokan mi ro mo 

   Ma f’emi nikan sile 

   Gba mi, si tu mi ninu

   lwo ni mo gbekele 

   lwo n’iranlowo mi 

   Masai f’iye apa Re 

   D‘abo b’ori aibo mi.


3. Kristi ‘Wo nikan ni mo fe 

   N’nu Re, mo r’ohun gbogbo 

   Gb’enit’o subu dide 

   W’alaisan, at’afoju

   Ododo l’oruko Re 

   Alaisododo l'emi 

   Mo kun fun ese pupo 

   Iwo kun fun ododo.


4. ‘Wo l’opo ore-ofe 

   Lati fi bor’ese mi 

   Jeki omi iwosan 

   We inu okan mi mo; 

   lwo l’orisun iye

   Je ki mbu n’nu Re l‘ofe 

   Ru jade n‘nu okan mi 

   Si iye ainipekun. Amin

English »

Update Hymn