HYMN 271

C.M.S 169 H.C 151 6.7s (FE291)
“Emi o fi o sinu palapala apata”
 - Eks. 33:221. APATA aiyeraiye

   Se ibi isadi mi

   Jeki omi on eje

   T’o nsan lati iha Re 

   Se iwosan f’ese mi

   K’o si so mi di mimo.


2. K‘lse ise owo mi,

   Lo le mu ofin Re se

   B’itara mi ko l’are

   T’omije mi nsan titi

   Nwon ko to fun etutu 

   Wo nikan l’o le gbala.


3. Ko s‘ ohun ti mo mu wa 

   Mo ro mo agbelebu

   Mo wa, k'o d’aso bo mi 

   Mo nwo O fun iranwo 

   Mo wa sib’orisun ni

   We mi, Olugbala mi.


4. ‘Gbati emi mi ba nlo 

   T'iku ba p'oju mi de

   Ti mba nlo s'aiye aimo 

   Ti nri o n'ite ‘dajo

   Apata aiyeraiye

  Se ibi isadi mi. Amin

English »

Update Hymn