HYMN 285
C.MS. 493 H.C 460 C.M (FE 299)
"Awon omode si nke ninu templi
wipe, Hosanna si omo Dafidi"
- Matt 21:15
1.  HOSANNA! e korin soke 
     S'omo nla Dafidi, 
     Pelu Kerub ati Seraf 
     K’a yin Om-Olorun.
2.  Hosanna! eyi na nikan 
     L'ahon wa le ma ko 
     Iwo ki okegan ewe
     Ti nkorin iyin Re.
3.  Hosanna! Alufa Oba, 
     Ebun Re ti po to!
     Eje Re lo je iye wa, 
     Ore Re ni onje wa.
4.  Hosanna! Baba, awa mu 
     Ore wa wa fun O,
     Ki se wura on ojia 
     Bikose okan wa.
5.  Hosanna! Jesu, lekan ri, 
     O yin awon ewe
     Sanu fun wa si f’eti si, 
     Orin awa ewe.
6.  Jesu, b' O ba ra wa pada 
     T‘a si wo ‘joba Re
     A o fi harpu wura ko 
     Hosanna titi lai.  Amin
English »Update Hymn