HYMN 299

H.C 186 L.M (FE 320) 
"Ki a ma ri pe emi nsogo, bikose ninu
agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa"
- Gal. 6:14 



1. GBATI mo ri agbelebu

   Ti a kan Oba ogo mo

   Mo ka gbogbo oro s‘ofo 

   Mo kegan gbogbo ogo mi.


2. K’a, ma se gbo pe, mo nhale, 

   B‘o ye n‘iku Oluwa mi 

   Gbogbo nkan asan ti mo fe

   Mo da sile fun eje Re.


3. Wo lat' ori, owo , ese 

   B‘ikanu at‘ife ti nsan 

   ‘Banuje at‘ife papo 

   A f'egun se ade Ogo.


4. Gbogbo aiye ba je t'emi

   Ebun abere ni fun mi

   Ife nla ti nyanilenu

   Gba gbogbo okan, 

   emi mi. Amin

English »

Update Hymn