HYMN 301

H.C. 199 (FE 322)
"O pari" - John 19:30 
Tune: “Ase ife Orun"1. IFE lo to bayi!

   Ohun gbogbo pari, 

   O ti pari gbogbo ise, 

   T’ o tori re w' aiye.


2. Ohun ti Baba fe, 

   Ni Jesus ti se tan: 

   Wahala ati iya Re,

   Mu Iwe Mimo se.


3. Ko si ‘rora wa kan,

   Ti Jesu ko je ri

   Gbogbo edun at‘ aniyan, 

   L’ okan Re si ti mo.


4. L’ ori t‘ a f' egun de,

   At’ okan Re mimo,

   L’ a ko gbogbo ese wa le,

   K‘O ba le wo sa san.


5. Ife lo mu k' O ku,

   Fun emi otosi;

   'Wo Etutu f‘ ese gbogbo,

   Mo f' igbagbo ro mo.


6. Nigba aini gbogbo, 

   Ati n' ite ‘dajo,

  Jesu, ododo Re nikan, 

  Ni igbekele mi.


7. Jo sise ninu mi, 

   Bi O ti se fun mi, 

   Si jeki ife mi si O, 

   Ma fi ore Re han. Amin

English »

Update Hymn