HYMN 305

C.M.S 198. t.H.c. 190 C.M.
“Eje Kristi iyebiye" - 1Pet. 1:191. OGO ni fun Jesu, 

   T’o f' irora nla, 

   Ta eje Re fun mi, 

   Lati iha Re.


2. Mo r‘ iye ailopin, 

   Ninu eje na; 

   lyonu Re sa po, 

   Ore Re ki tan.


3. Ope ni titi lai, 

   F'eje ‘yebiye,

   ‘T o ra aiye pada, 

   Kuro n’nu egbe.


4. Eje Abel' nkigbe, 

   Si orun f' esan; 

   Sugb’ eje Jesu nke, 

   Fun ‘dariji wa.


5. Nigbati a bu won, 

   Okan ese wa, 

   Satan, n' idamu re, 

   F'eru sa jade.


6. Nigbat’ aiye ba nyo, 

   T’ongbe ‘Yin Re ga, 

   Awon ogun Angel, 

   A ma f' ayo gbe.


7. Nje, e gbohun nyin ga, 

   Ki iro na dun!

   Kikan lohun goro,

   Yin Od' agutan. Amin

English »

Update Hymn