HYMN 307

ORO MEJE KRISTI LORI AGBELEBU

H.C. 200 7s. 6. (FE 328)
"Baba dariji won; nitori t nwon ko mo
ohun ti nwon se." - Luku 23:341. IWO to bebe f'ota Re,

   L'or'igi agbelebu: 

   Wipe, “fiji won Baba,"

   Jesu, sanu fun wa.


2. Jesu, jo bebe fun wa, 

   Fun ese wa ‘gbagbogbo; 

   A ko mo ohun t’n se, 

   Jesu, sanu fun wa.


3. Jek’ awa ti nwa anu, 

   Dabi Re l ‘kan n’ iwa, 

   ‘Gbat’aba se wa n’ibi: 

   Jesu, sanu fun wa.


“Loni ni iwo o wa pelu mi ni 
paradise." - Luku 23:43


4. Jesu, ‘Wo t’o gbo aro, 

   Ole t’ oku l’ egbe Re, 

   T’ o si mu d’ orun rere: 

   Jesu, sanu fun wa.


5. Ninu ebi ese wa,

   Jek’ a toro anu Re,’ 

   K' a ma pe oruko Re: 

   Jesu, sanu fun wa.


6. Ranti awa ti nrahun, 

   T‘ a nwo agbelebu Re; 

   F’ ireti mimo fun wa, 

   Jesu, sanu fun wa.

"Obinrin, wo Omo re, wo iya re."
- John. 19:26, 27


7. Wo t'o fe l'afe dopin 

   Iya Re t'o n kanu Re,

   Ati ore Re owon:

   Jesu saanu fun wa.


8. Jek'apin n'nu iya Re,

   K' a ma ko iku fun O,

   Jek’ a ri ‘toju Re gba: 

   Jesu, sanu fun wa.  


9. Ki gbogbo awa Tire,

   Je omo ile kanna;

   Tori Re, k’a fe ‘ra wa:

   Jesu, sanu fun wa.


“Olorun mi, Olorun mi, ese ti iwo 
fi ko mi sile.” - Matt. 27:46

10. Jesu, ‘Wo ti eru mba, 

    ‘Gbat’ o si ku Wo nikan, 

    Ti okunkun su bo O: 

    Jesu, sanu fun wa.


11. ‘Gbati a ba npe lasan, 
 
    T’ ireti wa si jina; 

    N’nu okun na di wa mu;

    Jesu, sanu fun wa.


12. B’od dabi Baba kogbo, 
  
    B’ o dabi ‘moleko si,

    Jek’ a f' igbagbo ri O, 

    Jesu, sanu fun wa.


“Orungbe ngbe mi." ‐ John 19:30B


13. Jesu, ninu ongbe Re, 

    Ni ori agbelebu, 

    ‘Wo ti o fe wa sibe; 

    Jesu, sanu fun wa.


14. Ma kongbe fun wa sibe, 

    Sise mimol’ ara wa;

    Te ife re na l’orun; 

    Jesu, sanu fun wa.


15. Jek’ a kongbe ife Re, 

    Ma samona wa titi, 

    Si'bi omi iye ni: 

    Jesu, sanu fun wa.


“O pari." - John. 19:30


16. Jesu Olurapada,

    ‘Wo t’ o se ‘fe Baba Re, 

    T' o si jiya’tori wa; 

    Jesu, sanu fun wa.


17. Gba wa I'ojo idamu, 

    Se oluranlowo wa, 

    Lati ma t’ona mimo: 

    Jesu, sanu fun wa.


18. F’ imole Re s’ ona wa, 

    Ti y’o ma tan titi lai, 

    Tit'ao fi de odo Re: 

    Jesu, sanu fun wa. etc.


"Baba Ii owe Re ni mo fi emi mi 
le" - Luku 23:46


19. Jesu, gbogbo ise re, 

    Gbogbo idamu Re pin; 

    O jow’ emi Re lowo: 

    Jesu, sanu fun wa.


20. ‘Gbat’ iku ba de ba wa: 

    Gba wa lowo ota wa; 

    Yo wa wakati na: 

    Jesu, sanu fun wa.


21. Ki iku at’ iye Re,

    Mu Oore-ore ba wa,

    Ti yio mu wa d‘oke: 

    Jesu, sanu fun wa. Amin

English »

Update Hymn