HYMN 308

(FE 329)
"Nitori ore-ofe ni a ngba nyin la"
- Efe. 2:8 



1. EKUN ko le gba mi,

   Bi mo le f'ekun we 'ju;

   Ko le mu eru mi tan,

   Ko le we ese mi nu;

   Ekin ko le gba mi.

Egbe: Jesu sun, O ku fun mi,

      O jiya lori igi

      Lati so mi d'ominira

      On na l'O le gba mi.


2. lse ko le gba mi

   lse mi t‘o dara ju

   Ero mi t'o mo julo

   Ko le s'okan mi d'otun 

   Ise ko le gba mi.

Egbe: Jesu sun, O ku fun mi...


3. ‘Duro ko le gba mi 

   Enit‘o junu ni mi

   L‘eti mi l’anu nke pe

   Bi mo ba duro ngo ku 

   ‘Duro ko le gba mi.

Egbe: Jesu sun, O ku fun mi...


4. Igbagbo le gba mi 

   Jeki ngbekel'Omo Re 

   Jeki ngbekele s’ise Re

   Jeki nsa si apa Re

   Igbagbo le gba mi.

Egbe: Jesu sun, O ku fun mi,

      O jiya lori igi

      Lati so mi d'ominira

      On na l'O le gba mi. Amin

English »

Update Hymn