HYMN 317

(FE 340)
ORIN AjKINDE JESU
"E ma ko Orile ede gbogbo" - Matt. 28:191. LO kede ayo na fun 

   gbogho aiye

   P‘Omo Olorun segun iku

   Fi iyin-tiyin pel’ayo rohin na, 

   Emi Mimo to gunwa.

Egbe: Oba mi de!

      Asegun mi de! 

      Ogo, Ola at'agbara ati 'pa 

      F 'Odagutan to gunwa.


2. lyin Jesu l’awon

   Ange li nke

   T'o wa ra 'raiye pada

   Okan soso ajanaku ni Jesu, 

   T'o m'aiye pelu orun.

Egbe: Oba mi de!...


3. Kabiyesi Oba Alaiyeluwa 

   Metalokan Alagbara

   Awamaridi Olodumare

   T’o nse ise iyanu.

Egbe: Oba mi de!...


4. ltiju nla d a bo awon ika 

   T‘o kan Oluwa wa mo 'gi 

   Rikisi ikoko ota ti d' asan 

   Olugbala ji dide. 

Egbe: Oba mi de!...


5. Bi orile-ede enia dudu

   Ati ka wa si eweko

   Sugbon awa ni Baba kan l’oke 

   T’o mo pe ‘se Re ni wa.

Egbe: Oba mi de!...


6. Ayo t’o wa ninu Ajinde 

   Jowo fun wa Olugbala 

   ’Gbat’a ba yo si O Eleda wa 

   K’awa le gb’ade ogo.

Egbe: Oba mi de!...


7. Awa f‘ogo fun Baba wa l‘oke 

   A tun f'ogo fun Omo Re

   Awa tun f’ogo fun O Emi Mimo

   Metalokan l‘ope ye.

Egbe: Oba mi de!

      Asegun mi de! 

      Ogo, Ola at'agbara ati 'pa 

      F 'Odagutan to gunwa. Amin

English »

Update Hymn