HYMN 32

C.M.S 34, H.C 220, C.M (FE 49) 
"Eyi ni ojo ti Oluwa da" - Ps. 118:24


1. EYI I'ojo t'Oluwa da,

   O pe ‘gba na ntire

   K'orun k‘o yo, k‘aiye ko yo 

   K’iyin yi 'te na ka.


2. Loni, o jinde ‘nu oku

   ljoba Satan tu

   ‘Won mimo tan ‘segun Re ka, 

   Nwon nsoro ‘yanu Re.


3. Hosanna si Oba t‘a yan

   S‘Omo Mimo Dafidi 

   Oluwa, jo sokale wa, 

   T’ lwo t‘igbala Re.


4. Abukun l‘Oluwa t'o wa 

   N'ise ore-ofe

   T'o wa l‘Oruko Baba Re, 

   Lati gba ‘ran wa la.


5. Hosanna li ohun goro, 

   L’orin ljo t’aiye

   Orin t'oke orun lohun 

   Yio dun ju be lo. Amin

English »

Update Hymn