HYMN 322

(FE 345)
C.M.S 222 t.H.C 383 6s 8s
“Nigbati nwon wo inu iboji, won
ko si ba oku Jesu Oluwa" - Luku 24:31. OLUWA ji loto 

   Olugbala dide

   O f‘agbara Re han 

   L'or‘orun apadi

   N'iberu nla, awon eso 

   Subu lule, nwon si daku.


2. Wo, egbe angeli

   Pade l'ajo kikun

   Lati gbo ase Re

   Ati lati juba

   Nwon f‘ayo wa, nwon si nfo lo 

   Lati orun si ‘boji na.


3. Nwon tun fo lo s‘orun

   Nwon mu ‘hin ayo lo 

   Gbo iro orin won 

   Bi nwon si ti nfo lo 

   Orin won ni, Jesu t'o ku 

   Ti ji dide, o Ji Ioni.


4. Enyin t‘a ra pada

   E gberin ayo na

   Run iro re kiri 

   Si gbogbo agbaiye

   E ho f'ayo, Jesu t‘o ku 

   Ti ji dide, ki y‘o ku mo.


5. Kabiyesi! Jesu!

   T‘o Feje Re gba wa

   Ki iyin Re jale

   lwo t’o ji dide

   A ba O ji, a si joba

   Pelu Re lai, l'oke orun. Amin

English »

Update Hymn