HYMN 324

CMS 224 H.C. 205 D.C.M (FE 347)
"Ji, ohun-elo orin mimo ati durur: emi
tikarami o si ji ni kutukutu" - Ps. 108:21. JI, Ji okan ayo ji, ji

   Oluwa re jinde

   Lo 'boji Re, k'o si mura

   Okan ati korin

   Gbogbo eda l'o si ti ji

   Ti nwon nkorin didun

   Itanna 'kini t'o ko tan

   Leba odo lo hu.


2. Isu dede aiye y'o lo

   L'ojo ajinde yi

   Iku ko si mo n'nu Kristi

   Iboji ko n'ipa

   Ninu Kristi l'a nwa, t'a nsun

   T'a nji, t'a si ndide

   Omije t'iku mu ba wa

   Ni Jesu y'o nu nu.


3. Ki gbogbo 'eiye ati igi

   At' itana ti ntan,

  Ki nwon so ti isegun Re

  Ati t'ajinde Re

  Papa, e gbohun nyin soke

  E bu s'orin ayo!

  Enyin oke, e si gberin

  Wipe, Iku ti ku.


4. Okan ayo, e ji, e wa

   Oluwa t’o jinde

   E yo ninu ajinde Re

   K’oro Re tu nyin n’nu

   E gbohun nyin soke, ke yin 

   Enit' o ji dide

   L’ohun kan ni ka gberin pe 

   "Jesu jinde fun mi."  Amin

English »

Update Hymn