HYMN 327

(FE 350) H.C 214 D. 8s 7s 
"Aye ireti nipa ajinde Jesu"
- 1 Peter 1:31. HALLELUYAH Halleluyah! 

   E gbe ohun ayo ga

   E ko orin inudidun 

   K’e si yin Olorun wa!

   Enit’ a kan m‘agbelebu

   T‘o jiya fun ese wa

   Jesu Kristi Oba ogo 

   Jinde kuro n‘nu oku.


2. lrin idabu se kuro

   Kristi ku O si tun ye

   O mu iye ati aiku

   Wa l‘oro ajinde Re

   Kristi ti segun, awa segun 

   Nipa agbara nla Re

   Awa o jinde pelu Re

   A o ba wo ‘nu Ogo.


3. Kristi jinde, akobi ni 

   Ninu awon t’o ti sun 

   Awon yi ni y'o ji dide 

   Ni abo Re ekeji

   lkore ti won ti pon tan 

   Nwon nreti Olukore 

   Eniti y‘o mu won kuro 

   Ninu isa oku‘won.


4. Awa jinde pelu Kristi

   To nfun wa l'ohun gbogbo 

   Ojo, iri, ati ogo

   To ntan jade loju Re 

   Oluwa, b‘a ti wa l'aiye

   Fa okan wa sodo Re 

   K'awon angeli sa wa jo 

   Ki nwon ko wa d‘odo Re.


5. Halleluyah, Halleluyah,

   Ogo ni fun Olorun 

   Halleluya f’Olugbala 

   Enit' O segun iku 

   Halleluya f‘Emi Mimo 

   Orisun ‘fe iwa mimo 

   Halleluyah, Halleluyah, 

   F’Olrun Metalokan. Amin

English »

Update Hymn