HYMN 335

11s (FE 358)
"Ma tesi waju Serafu Mimo"1. A KAN Krist‘lrekoja mo agbelebu 

   O kigbe oro wipe, “igbala pari" 

   O jowo emi re lowo fun irapada Eda 

   O sun ninu iboji, o di asegun.


Egbe: O jinde, O jinde 

      Jesu, Oba lye

      O jinde, O jinde 

      O jinde loni.


2. Jesu Oluwa Iye, o wa to ‘ku wo 

   Iku ati ipo oku ko tun n’ipa mo 

   E f'ogo fun Olorun, fun ‘segun lor'iku

   O so oro iku d’asan f'awa elese. 

Egbe: O jinde, O jinde ...


3. Oba Olupilese Iye ti jinde

   O di akobi ninu awon ti o sun 

   Wo Alfa at'Omega

   Ipilese at'opin

   Wo ni isika iku at'ipo oku.

Egbe: O jinde, O jinde ...


4. Jesu nip’ ajinde Re so emi wa ji 

   Ji wa n'nu iku ese s’iye ododo 

   K‘ajinde ara le je tiwa

   K’ife on Alafia

   Ma gbile ninu aiye gege bi t’orun. 

Egbe: O jinde, O jinde ...


5. Jesu Oluwa Iye se ‘lekun iku 

   F'om’egbe Serafu ati Kerubu 

   Iye ni tiwa titi l'aiye yi ati l’orun 

   Ao si joba pelu re lai ati lailai.

Egbe: O jinde, O jinde 

      Jesu, Oba lye

      O jinde, O jinde 

      O jinde loni. Amin

English »

Update Hymn