HYMN 338

C.M.S 237 D.7s (FE 361)
“Ago re wonni ti I‘ewa to"
- Ps. 84:11. ‘BUGBE Re ti l’ewa to! 

   Ni le ‘mole at'ife 

   ‘Bugbe Re ti l'ewa to! 

   Laiye ese at’osi

   Okan mi nfa nitoto 

   Fun idapo enia re 

   Fun imole oju Re 

   Fun ekun Re, Olorun.


2. Ayo ba awon eiye

  Ti nfo yi pepe Re ka 

  Ayo okan l'o simi 

  L'aiya Baba l'o poju

  Gege b'adaba Noa

  Ti ko r’ibi simi le 

  Nwon pada sodo Baba 

  Nwon si nyo tili aiye.


3. Nwon ko simi iyin won 

   Ninu aiye osi yi

   Omi nsun ni aginju

   Manna nt‘orun wa fun won 

   Nwon nlo Iat‘ ipa de ‘pa 

   Titi nwon fi yo si O

   Nwo si wole l'ese Re 

   T'O mu won la ewu ja.


4. Baba, je ki njere be 

   S'amona mi l'aiye yi 

   Fore ofe pa mi mo 

   Fun mi l'aye lodo Re 

   lwo l'orun at'Asa

   To okan isina mi 

   lwo l‘orisun ore 

   Ro ojo re sori mi. Amin

English »

Update Hymn