HYMN 341

1. MO n tesiwaju l’ona naa 

   Mo n g'oke si l’ojoojumo 

   Mo n gbadura bi mo ti n lo 

   Oluwa f'ese mi mu le.

Egbe: Oluwa joo gbe mi s'oke

      S'ile orun nipa gbagbo

      Bi t'ayo at'ife gbe wa

      Oluwa f'ese mi mu le.


2. lfe okan mi ko duro

   Laarin yemeji at'eru

   Awon miiran le maa gbe be 

   llepa mi n’ibi giga. 

Egbe: Oluwa joo gbe mi...


3. Em'o bori b'idanwo de 

   Okan mi yoo sinmi le O 

   Alaafia kikun si nbe 

   F‘awon t'o ngbe ibi giga.

Egbe: Oluwa joo gbe mi...


4. Mo fe de ‘bi giga julo

   B‘o ti wu ki‘ija naa le to 

   No ma ko’rin bi mo ti n lo 

   Oluwa joo mu mi de be. 

Egbe: Oluwa joo gbe mi...


5. Oluwa joo s'amona mi 

   Laisi Re n ko ni le de be

   Gba m‘ba si de ilu Orun

   Okan mi yoo f‘ope fun O. 

Egbe: Oluwa joo gbe mi s'oke

      S'ile orun nipa gbagbo

      Bi t'ayo at'ife gbe wa

      Oluwa f'ese mi mu le. Amin

English »

Update Hymn