HYMN 342

(FE 365) 
H.C 232 t.Apa II D. 8s 7s
"owo otun Re, ati apap Re mimo, Ii o ti 
mu igbala wa fun ara re" - Ps. 96:11. WO Asegun b’o ti goke 

   Wo Oba n'nu ola Re 

   Ogun keke ofurufu

   Lo s' orun agbala Re 

   Gbo orin awon Angeli 

   Halleluya ni nwon nko 

   Awon 'lekun si si sile 

   Lati gba Oba Orun.


2. Tani Ologo ti mbo yi 

   T'on ti ipe jubeli 

   Oluwa awon ‘mo-ogun 

   On to ti segun fun wa 

   O jiya lor'agbeleu 

   O jinde ninu oku

   O segun Esu at’ese 

   Ati gbogbo ota Re.


3. B'o ti nbuk‘awon ore Re 

   A gba kuro lowo won

   Bi oju nwon si ti nwo lo 

   O nu nin’ awosanmo 

   Enit' o ba Olorun rin 

   T’o si nwasu otito 

   On, Enoku wa, l’a gbe lo 

   S‘ile Re loke orun.


4. On, Aaron wa, gbe eje Re, 

   Wo inu ikele lo

   Josua wa, ti wo Kenaan 

   Awon oba nwariri

   A fi 'di eya Israel 

   Mule nibi ‘simi won 

   Elija wa si fe fun wa 

   N'ilopo meji Emi.


5. lwo ti gbe ara wa wo

   Lo s'ow' otun Olorun

   A si joko nibi giga

   Pelu Re ninu ogo

   Awon Angeli mbo Jesu 

   Enia Joko Ior'ite

   Oluwa, b‘lwo ti goke 

   Jo je k'a le goke be. Amin

English »

Update Hymn