HYMN 343

H.C 226. 7s (FE 366)
"Bi o ti nsure fun won, a ya kuro
lodo won, a si gbe e lo si Orun"
 - Luku 24:511. ALAFIA f’ojo na, Alleluya!

   T’o pada s'ite l'orun, Alleluya! 

   Odagutan elese, Alleluya! 

   Goke orun giga lo, Alleluya!2. lyin nduro de nibe, Alleluya! 

   Gb’ori nyin enyin ‘lekun, Alleluya! 

   Gba Oba ogo sile, Alleluya!

   Enit' o segun iku, Alleluya!


3. Orun gba Oluwa re, Alleluya! 

   Sibe, O feran aiye, Alleluya!

   B'o ti pada s'orite, Alleluya!

   O np’eda ni t'On sibe, Alleluya!


4. Wo, O gbowo Re sake, Alleluya! 

   Wo, O f'apa ife han, Alleluya! 

   Gbo, bi On ti nsure fun, Alleluya! 

   Ijo Re laiye nihin, Alleluya!


5. Sibe, O mbebe fun wa, Alleluya! 

   lku Re l'o fi mbebe, Alleluya!

   O npese aye fun wa, Alleluya! 

   On l'akobi iran wa, Alleluya!


6. Oluwa, b'a ti gba O, Alleluya!

   Jina kuro lodo wa, Alleluya! 

   M‘okan wa lo sibe na, Alleluya! 

   K'a wa O loke orun, Alleluya! Amin

Yoruba »

Update Hymn