HYMN 346

(FE 369)
"E gbe orin nyin soke" - Ps. 24:91. E GB'ori nyin soke enu ona, 

   K’Oluwa ogo wole

   Enit’ O f‘eje re r’aiye pada 

   O mbo lati gba ‘joba. 

Egbe: Hosannah, enyin Orun

      Halleluyah, eyin Aiye,

      Orun, Osupa, e wole 

      Kabiyesi, f 'Oba wa.


2. Awa Iran Israeli ni Afrika 

   E gb‘ola Oluwa ga

   Ajagun -molu Wa ti goke lo 

  Lati lo pese aye. 

Egbe: Hosannah, enyin Orun...


3. Wo, Oba wa ninu Olanla Re, 

   Gun keke Ofurufu

   Agogo Orun pelu korin lyin 

  ‘Ghat’Oba Ogo wole. 

Egbe: Hosannah, enyin Orun...


4. Okan mi nfa s‘Agbala ayo na 

   Nibiti Kristi gunwa

   Odi yika ati Agbala Re

   Wura l'a fi se loso. 

Egbe: Hosannah, enyin Orun...


5. Agbara Merinlelogun wole

   Pelu ade wura won

   At'awon Eda Alaye merin

  Nwon nfi iye fo f 'ayo. 

Egbe: Hosannah, enyin Orun

      Halleluyah, eyin Aiye,

      Orun, Osupa, e wole 

      Kabiyesi, f 'Oba wa. Amin

English »

Update Hymn