HYMN 349

H.C227D.75(FE372)
"A gbe e soke awosanma si gba a
kuro l’oju won" - Ise 1:91.  O ti lo, Awosanma 

Ti gba kuro loju wa 

Soke orun nibiti 

Oju wa ko le tele 

Oti kuro l’aiye yi

O ti de ibi mimo 

Lala at’irora tan

lja tan, O ti segun.


2.  O ti lo, Awa si wa

L’ aiye ese at'iku

A ni ‘se lati se fun

L’aiye t’o ti fi sile

K’a si tele ona Re:

K’a tele tokantokan

K’a s’ota re di ore

K'a fi Kristi han n'iwa wa.


3.  O ti lo, On ti wipe

"O dara ki Emi lo"

Ni ara sa l’o ya wa 

Sugbon or'ofe Re wa 

On ni awa ko ri mo

A ni Olutunu re

Emi Re si je tiwa

On ns’agbara wa d‘otun.


4.  O ti lo, L’ona kanna 

K‘o ye k‘ljo Re ma lo 

K'a gbagbe ohun ehin 

K’a si ma te si waju 

Oro re ni ‘mole wa 

Titi de opin aiye 

Nibiti oto Re wa

Y‘o pese fun alaini.


5.  O ti lo, Lekan si i, 

A o tun f’oju wa ri

O wa b’o ti wa l’aiye 

Gege b‘o ti wa l’aiye 

N'nu bugbe t‘o wa nibe 

Y‘o pese aye fun wa 

Ninu aiye ti mbo wa,

A o  j'okan pelu Re.


6.  O ti lo, Fun ire wa

Eje a duro de

Ojinde, ko si nihin

O ti goke re orun 

Je k‘a gb'okan wa soke 

Sibiti Jesu ti lo

Si odo Olorun wa, 

Nibe l’alafia wa.  Amin

English »

Update Hymn