HYMN 35

C.M.S. 29 o.t. H.C 17, L.M (FE 52) 
“Omo Enia li Oluwa ojo isinmi"
- Matt 12:8


1. OLUWA ojo isimi,

   Gbo tiwa, pelu wa loni 

   Awa pade fun adura

   A fe gb’oro T’o fi fun wa.


2. Isimi t’aiye yi rorun 

   Sugbon isimi t’orun dun 

   Lala okan wa fe ‘jo na 

   T'a o simi lailese da.


3. Ko s’ija, ko si ‘dagiri

   Ko s’aniyan bi t’aiye yi 

   T‘y’o dapo mo ikorin wa, 

   T’o nt’ete aiku jade wa.


4. Bebe, ojo t’a ti nreti 

   Afemoju re l’a fe ri

   A fe yo Iona ise yi,

   K’a sun n’iku, k’a ji l’ayo. Amin

English »

Update Hymn