HYMN 350

(FE 373)
C.M.S 577, H.C 391 tabi A. & M 
396 8s. 7s
"Jerusalemu Mimo" - lfihan 21:101.  SALEM t'orun ilu ‘bukun 

T'okun fun ‘fe at'ayo

Ti af’okuta aye ko

Ni orun giga loke 

Pel’ogun angeli yika

Ton nsokale b’iyawo.


2.  Lat'ode orun lohun wa, 

L’o ti wo aso ogo

To ye eniti o fe o

Ao sin o f'oko re 

Gbogbo ita at’odi re 

Je kiki oso wura.


3.  Ilekun re ndan fun pearli 

Nwon wa ni sisi titi 

Awon oloto wo ‘nu re 

Nip’ eje Olugbala

Awon to fara da ‘ponju 

Tori oruko Jesu.


4.  Wahala at’iponju nla 

L’o s'okuta re lewa 

Jesu papa l'Eni to won, 

S’ipo ti o gbe dara

Ife inu Re san ni pe 

K'a le s’afin Re loso.


5.  Ogo at'ola fun Baba 

Ogo at’ola fun Omo 

Ogo at’ola fun Emi 

Metalokan titi lai 

At’aiyeraiye okanna, 

Bakanna titi aiye.  Amin

English »

Update Hymn