HYMN 352

(FE 375) C.M.S 249 H.C 24, 11s 
“Eniti o ba segun ni yio jogun 
nkan wonyi” - Ifi. 21:71. ILE ewa wonni, b’o ti dara to 

   Ibugbe Olorun, t’oju ko ti ri

   Tal’ o fe de ibe, lehin aiye yi? 

   Tal’o fe k‘a wo on ni aso funfun.


2. Awon wonni ni, t’oji nin’ orun won

   Awon t‘o ni gbagbo si nkan t'a ko ri 

   Awon t‘o k’aniyan won l’Olugbala 

   Awon ti ko tiju agbelebu Krist.


3. Awon ti ko nani gbogbo nkan aiye 

   Awonm t’o le soto de oju iku 

   Awon t’o nrubo ife L’ojojumo 

   Awon ta f ’igbala Jesu ra pada.


4. ltiju ni fun nyin, om'ogun Jesu 

   Enyin ara ilu ibugbe orun 

   Kinla! e nfi fere at’ilu sire

   'Gbat’ o ni k’e sise t'o si pe, E ja!


5. B'igbi omi aiye si ti nkolu wa 

   Jesu Oba ogo, so si wa leti

   Adun t'o wa l'orun, ilu mimo ni, 

   Nibit’ isimi wa lai ati lailai. Amin

English »

Update Hymn