HYMN 356

C.M.S 422, K. (FE 379) 
306 t.H.C 106 6. 7s
"Kiyesi i, iru ife ti Baba fi fun wa pe 
ki a Ie ma pe wa li omo Olorun"
- 1John 3:1
1. ALABUKUN n'nu Jesu 

   Ni awon om'Olorun

   Ti a fi eje re ra

   Lat’ inu iku s'iye.

Egbe: A ba je ka wa mo won

      L'aiye yi, ati I'orun.


2. Awon ti a da l'are 

   Nipa ore-ofe Re

   A we gbogbo ese won 

   Nwon o bo lojo ‘dajo.

Egbe: A ba je ka wa mo...


3. Nwon s‘eso ore-ofe

   Ninu ise ododo

   Irira l‘ese si won 

   Or'Olorun ngbe ‘nu won.

Egbe: A ba je ka wa mo...


4. Nipa Ej'Odagutan 

   Nwon mba Olorun kegbe

   Pelu Ola-nla Jesus

   A wo won l'aso ago.

Egbe: A ba je ka wa mo won

      L'aiye yi, ati I'orun. Amin

English »

Update Hymn