HYMN 358

(FE 381) s.d.m.r.d.s.l.l d.t.d.l.s: 
"OIorun wipe ki imole ki o wa" 
- Gen. 1:31. BABA to da orun meje 

   Ati ‘le meje pelu

   Aiye lo se ekedogun 

   lyin ni f’oruko Re. 

Egbe: Ijinle loro na 

      Awamaridi si ni, 

      Ijinle loro na 

      Awamaridi si ni.


2. Orun, Osupa, Irawo 

   Awon ni ‘mole aiye 

   Okuta Oniyebiye 

  Awon ni ‘mole ‘sale. 

Egbe: Ijinle loro na...


3. Abo Oluwa Onike 

   L’awa Egbe bora mo

   Ko s‘ohun ‘bi to le se wa 

   Lagbara Metalokan.

Egbe: Ijinle loro na...


4. Eni loyun a bimo la 

   Agan a t’owo b‘osun 

   Olomo ko ni padanu 

   Iku ko ri wa gbe se.

Egbe: Ijinle loro na...


5. Ko s’eniti nri ‘di okun 

   A ki nri ‘di olosa

   Baba to da orun on aiye

   Ma je k’aiye r’idi mi.

Egbe: Ijinle loro na...


6. Awon Agbara Emi meje

   Ta fi wo HOLY MICHAEL 

   To si fi segun Lusifa

   Lojo ogun Olorun.

Egbe: Ijinle loro na...


7. Baba, Omo, Emi Mimo 

   Metalokan to gunwa 

   Jowo ko gbo adura wa, 

   Larin Egbe Serafu.

Egbe: Ijinle loro na 

      Awamaridi si ni, 

      Ijinle loro na 

      Awamaridi si ni. Amin

English »

Update Hymn