HYMN 359

1. Ejuba Olorun, wa, Jah 

   Oba onife julo 

   Olubori, Ajabori,

   Oba Orun on Aiye, 

Egbe: Ijinle loro na, 

      Awamaridi si ni.


2. Bayi l’o dawon eda Re 

   B’o ti wu O l’o da won 

   Awimayehun sa ni O 

   Awamaridi ni O.

Egbe: Ijinle loro na...


3. Nibit'ona ko ti si ri 

   Nibe ni ‘joko mi wa 

   Nip'agbara at’asa mi 

   Larin awon enia mi. 

Egbe: Ijinle loro na...


4. A ha ri eni le pada

   Gba mba nsise ogo mi 

   Awon Angel’ to l‘agbara 

   Nwon ko je dan eyi wo. 

Egbe: Ijinle loro na...


5. Lusifa t‘o l’agbara ju 

   Gbogbo awon Angel‘ lo 

   O f’owo pa ‘da mi loju 

   O si d’eni ifibu.

Egbe: Ijinle loro na...


6. Egbegberun ogun orun 

   L’o nso ti agbara mi, 

   Ogo, Ola ati ‘pa mi 

   Nwon njuba Agbara mi. 

Egbe: Ijinle loro na...


7. Sibe Emi ko yan eyi

   T’o ga julo ninu won 

   Sugbon Maikel t‘o kereju 

   Ni mo gbega ninu won. 

Egbe: Ijinle loro na...


8. Agbara ninu Agbara 

   Ogo, Ola at’ipa 

   Teru, teru, tifetife, 

   lfe si l’oruko mi.

Egbe: Ijinle loro na, 

      Awamaridi si ni. Amin

English »

Update Hymn