HYMN 361

H.C 244 6s 4s (FE 383)
"O ti pese ilu nla kan sile fun won"
- Heb. 11:161. JERUSALEM t'orun 

   Orin mi, ilu mi 

   Ile mi bi mba ku 

   Ekun ibukun mi: 

Egbe: Ibi ayo! 

      Nigbawo ni 

      Ngo r'oju re 

      Olorun mi?


2. Odi re, ilu mi

   L'a fi pearl se l’oso 

   ‘Lekun re ndan fun ‘yin 

   Wura ni ita re!

Egbe: Ibi ayo!...

3. Orun ki ran nibe 

   Beni ko s'osupa

   A ko wa iwonyi 

   Kristi n‘imole ibe.

Egbe: Ibi ayo!...


4. Nibe ni mo le ri 

   Awon Aposteli 

   At‘awon akorin

   Ti nlu harpu wura.

Egbe: Ibi ayo!...


5. Ni agbala wonni

   Ni awon Martyr wa 

   Nwon wo aso ala 

   Ogo bo ogbe won. 

Egbe: Ibi ayo!...


6. T'emi yi sa su mi

   Ti mo ngb'ago kedar! 

   Ko si ‘ru yi loke

   Nibe ni mo fe lo.

Egbe: Ibi ayo! 

      Nigbawo ni 

      Ngo r'oju re 

      Olorun mi? Amin

English »

Update Hymn