HYMN 363

(FE 385)
C.M.S 413 t. H.C 553, 8s 7s
“Nwon gbe jesu wa si Jerusalemu 
Iati fi fun Oluwa.” - Luku 2:21. ENYIN wo ni tempili Re 

   Oluwa t’a ti nreti

   Woli ‘gbani ti so tele 

   Olorun m’oro Re se

   Awon ti a ti ra pada 

   Yio fi ohun kan yin.


2. L'apa wundia iya Re

   E sa wo bi O ti sun

   Ti awon alagba ni si nsin

   Ki nwon to ku ‘nu ‘gbagbo 

   Halleluya, Halleluya, 

   W'Olorun Oga Ogo.


3. Jesu, nipa ifihan Re

   O ti gba iya wa je 

   Jo, je ka ri 'gbala nla Re 

   Mu ‘leri Re se si wa

   Mu wa lo sinu ogo Re 

   Sodo Baba Mimo ni.


4. ‘Wo Alade igbala wa 

   K’ife Re je orin wa 

   Jesu, Iwo l’a fiyin fun 

   Ni t’aiye t’O ra pada 

   Pelu Baba ati Emi 

   Oluwa Eleda wa. Amin

English »

Update Hymn