HYMN 365

(FE 387)
Golden Bells. No 432 S.S & S 599
“Oke giga kart hau" - I l l . 21:101. ILE ayo kan wa l’oke 

   Ti o ndan ti o si l‘ewa

   Ayo ibe ki si d’opin 

   L’osan tabi l’oru 

   Awon Angeli nkorin 

   Y‘ite Mimo na ka 

   Nigbawo lao ri O

   lle to dara julo. 

Egbe: A! ile didan, 

      A! ile didan

      Ile Olugbala, 

      ile to l’ogo julo.


2. Kerubu ati Serafu

   E je k’a yin Oluwa 

   Fun idasi wa lojo oni 

   Iyin fun Metalokan 

   Se ranti p’Oluwa mbo 

   Lati ko wa lo sile 

   Nigbawo lao ri O

   Ile t'o dara julo.

Egbe: A! ile didan...


3. Kikankikan l’Oluwa npe 

   Eda ko si mira

   Ikore si nfe ka

   E je k’a sa fun ese

   Ki Jesu le we wa mo 

   Ye fun ‘le nla l'oke 

   Nigbawo lao ri O 

   Ile t‘o dara julo.

Egbe: A! ile didan...


4. Awon to ti jagun koja

   Nwon nwo wa bi a ti nja 

   Nwon mha O agutan k‘egbe 

   Oba lo si je fun won

   lbanuje ko si n‘ibe 

   Ninu ile didan na

   Nigbawo lao ri O 

   Ile to dara julo.

Egbe: A! ile didan...


5. lwo ki yio jijakudi 

   K‘o ba Olugbala joba 

   Nibi Kerubu Serafu 

   Yi ite Olugbala ka 

   lbugbe Olugbala 

   T‘ao ma sin titi 

   Nigbawo lao ri O

   Ile to dara julo.

Egbe: A! ile didan...


6. Nigbat'o ba d'ojo kehin 

   Ti a o si de 'joba Re 

   K’a gbo ohun ayo yi pe 

   Bo s'ayo Oluwa re 

   Kerubu, Serafu, yo 

   E gb‘ade iye nyin 

   Nigbana lao ri O

   Ile to dara julo.

Egbe: A! ile didan, 

      A! ile didan

      Ile Olugbala, 

      ile to l’ogo julo. Amin

English »

Update Hymn